Native Bible

Daniel 5:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èyí ni àkọlé náà tí a kọ: Mene, mene, tekeli, peresini.

Daniel 5:25 in English

Daniel 5:25 · Berean Standard Bible

Now this is the inscription that was written: MENE, MENE, TEKEL, PARSIN.

Context

23Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. 24Nítorí náà, ó rán ọwọ́ tí ó kọ àkọlé yìí. 25“Èyí ni àkọlé náà tí a kọ: Mene, mene, tekeli, peresini. 26“Èyí ni nǹkan tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí: “Mene: Ọlọ́run ti ṣírò ọjọ́ ìjọba rẹ. Ó sì ti mú u wá sí òpin. 27“Tekeli: A ti gbé ọ lórí òsùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.