Native Bible

Daniel 5:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.

Daniel 5:23 in English

Daniel 5:23 · Berean Standard Bible

Instead, you have exalted yourself against the Lord of heaven. The vessels from His house were brought to you, and as you drank wine from them with your nobles, wives, and concubines, you praised your gods of silver and gold, bronze and iron, wood and stone, which cannot see or hear or understand. But you have failed to glorify the God who holds in His hand your very breath and all your ways.

Context

21A lé e kúrò láàrín ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn ẹranko; ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì ń jẹ koríko bí i ti màlúù; ìrì ọ̀run ṣì sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí tó fi mọ̀ pé, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ọmọ ènìyàn, òun sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú. 22“Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Belṣassari, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí. 23Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. 24Nítorí náà, ó rán ọwọ́ tí ó kọ àkọlé yìí. 25“Èyí ni àkọlé náà tí a kọ: Mene, mene, tekeli, peresini.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.