Native Bible

Amos 8:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán, Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.

Amos 8:9 in English

Amos 8:9 · Berean Standard Bible

And in that day, declares the Lord GOD, I will make the sun go down at noon, and I will darken the earth in the daytime.

Context

7Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé, “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe. 8“Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí? Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha ṣọ̀fọ̀? Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Naili, yóò sì ru ú sókè pátápátá bí ìkún omi a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Ejibiti. 9“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán, Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan. 10Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún. Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí yín. Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò. 11“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.