Amosi 8:7
Amos 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé, “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe.
Amos 8:7 in English
Amos 8:7 · Berean Standard Bible
The LORD has sworn by the Pride of Jacob: “I will never forget any of their deeds.
Context
5Tí ẹ ń wí pé,
“Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí
kí àwa bá à lè ta ọkà
kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin
kí àwa bá à le ta jéró?”
Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù
kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á
kí a sì fi òsùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ, 6kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà,
kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní,
kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀. 7Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé, “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe. 8“Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí?
Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha ṣọ̀fọ̀?
Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Naili,
yóò sì ru ú sókè pátápátá bí ìkún omi
a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Ejibiti. 9“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí,
“Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán,
Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.