Native Bible

Amos 8:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún. Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí yín. Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.

Amos 8:10 in English

Amos 8:10 · Berean Standard Bible

I will turn your feasts into mourning and all your songs into lamentation. I will cause everyone to wear sackcloth and every head to be shaved. I will make it like a time of mourning for an only son, and its outcome like a bitter day.

Context

8“Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí? Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha ṣọ̀fọ̀? Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Naili, yóò sì ru ú sókè pátápátá bí ìkún omi a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Ejibiti. 9“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán, Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan. 10Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún. Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí yín. Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò. 11“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 12Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti Òkun dé Òkun wọn yóò sì máa rìn ká láti gúúsù sí àríwá, wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.