Amosi 7:15
Amos 7:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’
Amos 7:15 in English
Amos 7:15 · Berean Standard Bible
But the LORD took me from following the flock and said to me, ‘Go, prophesy to My people Israel.’
Context
13Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.” 14Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore. 15Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’ 16Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé,
“ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli,
má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’ 17“Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí:
“ ‘Ìyàwó rẹ yóò di panṣágà ni ìlú,
àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú.
A ó fi okùn wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in
àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́.
Israẹli yóò sì lọ sí ìgbèkùn,
kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.