Amosi 7:13
Amos 7:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.”
Amos 7:13 in English
Amos 7:13 · Berean Standard Bible
But never prophesy at Bethel again, because it is the sanctuary of the king and the temple of the kingdom.”
Context
11Nítorí èyí ni ohun ti Amosi ń sọ:
“ ‘Jeroboamu yóò ti ipa idà kú,
lóòtítọ́ Israẹli yóò lọ sí ìgbèkùn,
jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ” 12Nígbà náà ni Amasiah sọ fún Amosi pé, “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Juda. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀, kí o sì máa sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀. 13Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.” 14Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore. 15Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.