Amosi 7:12
Amos 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Amasiah sọ fún Amosi pé, “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Juda. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀, kí o sì máa sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.
Amos 7:12 in English
Amos 7:12 · Berean Standard Bible
And Amaziah said to Amos, “Go away, you seer! Flee to the land of Judah; earn your bread there and do your prophesying there.
Context
10Nígbà náà Amasiah àlùfáà Beteli ránṣẹ́ sí Jeroboamu ọba Israẹli, wí pé: “Amosi ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárín gbùngbùn Israẹli. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀. 11Nítorí èyí ni ohun ti Amosi ń sọ:
“ ‘Jeroboamu yóò ti ipa idà kú,
lóòtítọ́ Israẹli yóò lọ sí ìgbèkùn,
jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ” 12Nígbà náà ni Amasiah sọ fún Amosi pé, “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Juda. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀, kí o sì máa sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀. 13Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.” 14Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.