Native Bible

Amos 7:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé, “ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli, má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’

Amos 7:16 in English

Amos 7:16 · Berean Standard Bible

Now, therefore, hear the word of the LORD. You say: ‘Do not prophesy against Israel; do not preach against the house of Isaac.’

Context

14Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore. 15Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’ 16Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé, “ ‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli, má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’ 17“Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí: “ ‘Ìyàwó rẹ yóò di panṣágà ni ìlú, àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú. A ó fi okùn wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́. Israẹli yóò sì lọ sí ìgbèkùn, kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.