Native Bible

Amos 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”

Amos 3:11 in English

Amos 3:11 · Berean Standard Bible

Therefore this is what the Lord GOD says: “An enemy * will surround the land; he will pull down your strongholds and plunder your citadels.”

Context

9Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti. “Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria; kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀ àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.” 10“Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí, “àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.” 11Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.” 12Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.” 13“Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.