Native Bible

Amos 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.

Amos 3:13 in English

Amos 3:13 · Berean Standard Bible

Hear and testify against the house of Jacob, declares the Lord GOD, the God of Hosts.

Context

11Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.” 12Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.” 13“Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. 14“Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀. 15Èmi yóò wó ilé òtútù lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru; ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé a ó sì pa ilé ńlá náà run,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.