Amosi 3:14
Amos 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀.
Amos 3:14 in English
Amos 3:14 · Berean Standard Bible
On the day I punish Israel for their transgressions, I will visit destruction on the altars of Bethel; the horns of the altar will be cut off, and they will fall to the ground.
Context
12Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì
kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan
bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli,
tí ń gbé Samaria kúrò
ní igun ibùsùn wọn
ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.” 13“Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. 14“Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run;
ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò
yóò sì wó lulẹ̀. 15Èmi yóò wó ilé òtútù
lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru;
ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé
a ó sì pa ilé ńlá náà run,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.