Amosi 3:10
Amos 3:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí, “àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”
Amos 3:10 in English
Amos 3:10 · Berean Standard Bible
“For they know not how to do right,” declares the LORD. “They store up violence and destruction in their citadels.”
Context
8Kìnnìún ti bú ramúramù
ta ni kì yóò bẹ̀rù?
Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀
ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀? 9Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu
àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti.
“Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria;
kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀
àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.” 10“Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí,
“àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.” 11Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;
yóò wó ibi gíga yín palẹ̀
a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.” 12Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì
kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan
bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli,
tí ń gbé Samaria kúrò
ní igun ibùsùn wọn
ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.