Amosi 2:6
Amos 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.
Amos 2:6 in English
Amos 2:6 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says: “For three transgressions of Israel, even four, I will not revoke My judgment, because they sell the righteous for silver and the needy for a pair of sandals.
Context
4Èyí ni ohun tí Olúwa wí,
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀,
wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́.
Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà,
òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé, 5Èmi yóò rán iná sí orí Juda
èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.” 6Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Wọ́n ta olódodo fún fàdákà
àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì. 7Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀,
bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára.
Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà,
láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. 8Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ,
lórí aṣọ tí wọ́n fi jẹ́ ẹ̀jẹ́
ní ilé òrìṣà wọn
wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.