Native Bible

Amos 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò rán iná sí orí Juda èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”

Amos 2:5 in English

Amos 2:5 · Berean Standard Bible

So I will send fire upon Judah to consume the citadels of Jerusalem.”

Context

3Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,” ni Olúwa wí. 4Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀, wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́. Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà, òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé, 5Èmi yóò rán iná sí orí Juda èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.” 6Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì. 7Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀, bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára. Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà, láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.