Native Bible

Amos 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli, èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run.

Amos 1:4 in English

Amos 1:4 · Berean Standard Bible

So I will send fire upon the house of Hazael to consume the citadels of Ben-hadad.

Context

2Ó wí pé, “Olúwa yóò bú jáde láti Sioni, ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá; ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, orí òkè Karmeli yóò sì rọ.” 3Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú, 4Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli, èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run. 5Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní àfonífojì Afeni run àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni. Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,” ni Olúwa wí. 6Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gasa, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú, ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbèkùn. Ó sì tà wọ́n fún Edomu,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.