Amosi 1:3
Amos 1:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú,
Amos 1:3 in English
Amos 1:3 · Berean Standard Bible
This is what the LORD says: “For three transgressions of Damascus, even four, I will not revoke My judgment,* because they threshed Gilead with sledges of iron.
Context
1Àwọn ọ̀rọ̀ Amosi, ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn Tekoa; ohun tí o rí nípa Israẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí Ussiah ọba Juda àti Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli. 2Ó wí pé,
“Olúwa yóò bú jáde láti Sioni,
ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá;
ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀,
orí òkè Karmeli yóò sì rọ.” 3Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi.
Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú, 4Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli,
èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run. 5Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku;
Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní àfonífojì Afeni run
àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni.
Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.