Native Bible

2 Samuel 22:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri; ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

2 Samuel 22:6 in English

2 Samuel 22:6 · Berean Standard Bible

The cords of Sheol entangled me; the snares of death confronted me.

Context

4“Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. 5Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri; tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. 6Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri; ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. 7“Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa, èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi. Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀ igbe mí wọ etí rẹ̀. 8Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì, ó sì mì, nítorí tí ó bínú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.