2 Samuẹli 22:5
2 Samuel 22:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri; tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
2 Samuel 22:5 in English
2 Samuel 22:5 · Berean Standard Bible
For the waves of death engulfed me; the torrents of chaos overwhelmed me.
Context
3Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,
àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi.
Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi;
ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá. 4“Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn,
ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. 5Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri;
tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. 6Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri;
ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. 7“Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa,
èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi.
Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀
igbe mí wọ etí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.