Native Bible

2 Samuel 22:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá, ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.

2 Samuel 22:20 in English

2 Samuel 22:20 · Berean Standard Bible

He brought me out into the open; He rescued me because He delighted in me.

Context

18Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. 19Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi, ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀yìntì mi. 20Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá, ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi. 21“Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi. 22Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.