Native Bible

2 Chronicles 8:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì tún kọ́ Tadmori ní aginjù àti gbogbo ìlú ìṣúra tí ó ti kọ́ ní Hamati.

2 Chronicles 8:4 in English

2 Chronicles 8:4 · Berean Standard Bible

He built Tadmor in the wilderness, in addition to all the store cities that he had built in Hamath.

Context

2Solomoni tún ìlú tí Hiramu ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀. 3Nígbà náà Solomoni lọ sí Hamati-Ṣoba ó sì borí rẹ̀. 4Ó sì tún kọ́ Tadmori ní aginjù àti gbogbo ìlú ìṣúra tí ó ti kọ́ ní Hamati. 5Ó sì tún kọ́ òkè Beti-Horoni àti ìsàlẹ̀ Beti-Horoni gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú. 6Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.