2 Kronika 8:3
2 Chronicles 8:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà Solomoni lọ sí Hamati-Ṣoba ó sì borí rẹ̀.
2 Chronicles 8:3 in English
2 Chronicles 8:3 · Berean Standard Bible
Then Solomon went to Hamath-zobah and captured it.
Context
1Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Solomoni kọ́ ilé Olúwa àti ilé òun fúnra rẹ̀. 2Solomoni tún ìlú tí Hiramu ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀. 3Nígbà náà Solomoni lọ sí Hamati-Ṣoba ó sì borí rẹ̀. 4Ó sì tún kọ́ Tadmori ní aginjù àti gbogbo ìlú ìṣúra tí ó ti kọ́ ní Hamati. 5Ó sì tún kọ́ òkè Beti-Horoni àti ìsàlẹ̀ Beti-Horoni gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.