2 Kronika 8:6
2 Chronicles 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí.
2 Chronicles 8:6 in English
2 Chronicles 8:6 · Berean Standard Bible
as well as Baalath, all the store cities that belonged to Solomon, and all the cities for his chariots and horses *—whatever he desired to build in Jerusalem, Lebanon, and throughout the land of his dominion.
Context
4Ó sì tún kọ́ Tadmori ní aginjù àti gbogbo ìlú ìṣúra tí ó ti kọ́ ní Hamati. 5Ó sì tún kọ́ òkè Beti-Horoni àti ìsàlẹ̀ Beti-Horoni gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú. 6Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí. 7Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kúrò láti ara àwọn ará Hiti, ará Amori, ará Peresi, ará Hifi àti ará Jebusi àwọn ènìyàn wọ̀nyí wọn kì í ṣe àwọn ará Israẹli, 8èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.