2 Kronika 18:19
2 Chronicles 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu ọba Israẹli lọ sí Ramoti Gileadi kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’ “Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún.
2 Chronicles 18:19 in English
2 Chronicles 18:19 · Berean Standard Bible
And the LORD said, ‘Who will entice Ahab king of Israel to march up and fall at Ramoth-gilead?’ And one suggested this, and another that.
Context
17Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?” 18Mikaiah tẹ̀síwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì. 19Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu ọba Israẹli lọ sí Ramoti Gileadi kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’
“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún. 20Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá síwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’
“ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ Olúwa béèrè. 21“ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’
“ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni Olúwa wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.