2 Kronika 18:20
2 Chronicles 18:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá síwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’ “ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ Olúwa béèrè.
2 Chronicles 18:20 in English
2 Chronicles 18:20 · Berean Standard Bible
Then a spirit came forward, stood before the LORD, and said, ‘I will entice him.’ ‘By what means?’ asked the LORD.
Context
18Mikaiah tẹ̀síwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì. 19Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu ọba Israẹli lọ sí Ramoti Gileadi kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’
“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún. 20Ní ìparí, ni ẹ̀mí kan wá síwájú, ó dúró níwájú Olúwa ó sì wí pé, ‘Èmi yóò tàn án.’
“ ‘Nípa ọ̀nà wo?’ Olúwa béèrè. 21“ ‘Èmi yóò lọ láti lọ di ẹ̀mí èké ní ẹnu gbogbo àwọn wòlíì.’
“ ‘Ìwọ yóò sì borí nínú ìtànjẹ rẹ̀ báyìí,’ ni Olúwa wí. ‘Lọ kí ó sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ 22“Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí Olúwa ti fi ẹ̀mí èké sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ. Olúwa sì ti sọ ibi sí ọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.