2 Kronika 18:17
2 Chronicles 18:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?”
2 Chronicles 18:17 in English
2 Chronicles 18:17 · Berean Standard Bible
Then the king of Israel said to Jehoshaphat, “Did I not tell you that he never prophesies good for me, but only bad?”
Context
15Ọba sì wí fún un pé, “Ìgbà mélòó ni èmi ó fi ọ́ búra láti sọ ohun kan fún mi bí kò ṣe ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní orúkọ Olúwa?” 16Mikaiah sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Israẹli túká kiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ” 17Ọba Israẹli wí fún Jehoṣafati pé, “Ṣe èmi kò sọ fún ọ wí pé òun kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kankan nípa mi rí, ṣùgbọ́n búburú nìkan?” 18Mikaiah tẹ̀síwájú pé, “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, mo rí Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ gbogbo ogun ọ̀run sì dúró lápá ọ̀tún àti lápá òsì. 19Olúwa sì wí pé, ‘Ta ni yóò tan Ahabu ọba Israẹli lọ sí Ramoti Gileadi kí ó sì lọ kú ikú rẹ̀ níbẹ̀?’
“Èkínní sì sọ tìhín, òmíràn sì sọ tọ̀hún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.