1 Samuẹli 28:7
1 Samuel 28:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.”
1 Samuel 28:7 in English
1 Samuel 28:7 · Berean Standard Bible
Then Saul said to his servants, “Find me a woman who is a medium, so I can go and consult her.” “There is a medium at Endor,” his servants replied.
Context
5Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi. 6Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì. 7Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.” 8Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.” 9Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.