Native Bible

1 Samuel 28:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.

1 Samuel 28:5 in English

1 Samuel 28:5 · Berean Standard Bible

When Saul saw the Philistine army, he was afraid and trembled violently.

Context

3Samuẹli sì ti kú, gbogbo Israẹli sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rama ní ìlú rẹ̀. Saulu sì ti mú àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà. 4Àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣunemu: Saulu sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gilboa. 5Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi. 6Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì. 7Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.