Native Bible

1 Samuel 28:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣunemu: Saulu sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gilboa.

1 Samuel 28:4 in English

1 Samuel 28:4 · Berean Standard Bible

The Philistines came together and camped at Shunem, while Saul gathered all Israel and camped at Gilboa.

Context

2Dafidi sì wí fún Akiṣi pé, “Nítòótọ́ ìwọ ó sì mọ ohun tí ìránṣẹ́ rẹ lè ṣe.” Akiṣi sì wí fún Dafidi pé, “Nítorí náà ni èmi ó ṣe fi ìwọ ṣe olùṣọ́ orí mi ni gbogbo ọjọ́.” 3Samuẹli sì ti kú, gbogbo Israẹli sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rama ní ìlú rẹ̀. Saulu sì ti mú àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà. 4Àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣunemu: Saulu sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gilboa. 5Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi. 6Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.