1 Samuẹli 28:9
1 Samuel 28:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”
1 Samuel 28:9 in English
1 Samuel 28:9 · Berean Standard Bible
But the woman replied, “Surely you know what Saul has done, how he has killed the mediums and spiritists in the land. Why have you set a trap to get me killed?”
Context
7Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.” 8Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.” 9Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.” 10Saulu sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.” 11Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?”
Òun sì wí pé, “Mú Samuẹli gòkè wá fún mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.