1 Samuẹli 28:10
1 Samuel 28:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.”
1 Samuel 28:10 in English
1 Samuel 28:10 · Berean Standard Bible
Then Saul swore to her by the LORD: “As surely as the LORD lives, no punishment shall come upon you for this.”
Context
8Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.” 9Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.” 10Saulu sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.” 11Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?”
Òun sì wí pé, “Mú Samuẹli gòkè wá fún mi.” 12Nígbà tí obìnrin náà sì rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Saulu sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Saulu ni ìwọ jẹ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.