Native Bible

1 Samuel 20:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Jonatani wí fún Dafidi pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a yóò fẹ́ ọ kù, nítorí ààyè rẹ yóò ṣófo.

1 Samuel 20:18 in English

1 Samuel 20:18 · Berean Standard Bible

Then Jonathan said to David, “Tomorrow is the New Moon, and you will be missed if your seat is empty.

Context

16Nígbà náà ni Jonatani bá ilé Dafidi dá májẹ̀mú wí pé, “Olúwa yóò pe àwọn àti Dafidi láti ṣírò.” 17Jonatani mú kí Dafidi tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí i, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀. 18Nígbà náà ni Jonatani wí fún Dafidi pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a yóò fẹ́ ọ kù, nítorí ààyè rẹ yóò ṣófo. 19Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí ibi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Eselu. 20Èmi yóò ta ọfà mẹ́ta sí ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀, gẹ́gẹ́ bí i pé mo ta á sí àmì ibìkan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.