Native Bible

1 Samuel 20:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Jonatani bá ilé Dafidi dá májẹ̀mú wí pé, “Olúwa yóò pe àwọn àti Dafidi láti ṣírò.”

1 Samuel 20:16 in English

1 Samuel 20:16 · Berean Standard Bible

So Jonathan made a covenant with the house of David, saying, “May the LORD hold David’s enemies accountable.”

Context

14Ṣùgbọ́n fi àìkùnà inú rere hàn mí bí inú rere Olúwa, níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè kí wọ́n má ba à pa mí. 15Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé. Bí Olúwa tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀tá Dafidi kúrò lórí ilẹ̀.” 16Nígbà náà ni Jonatani bá ilé Dafidi dá májẹ̀mú wí pé, “Olúwa yóò pe àwọn àti Dafidi láti ṣírò.” 17Jonatani mú kí Dafidi tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí i, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀. 18Nígbà náà ni Jonatani wí fún Dafidi pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a yóò fẹ́ ọ kù, nítorí ààyè rẹ yóò ṣófo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.