1 Samuẹli 20:17
1 Samuel 20:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jonatani mú kí Dafidi tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí i, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀.
1 Samuel 20:17 in English
1 Samuel 20:17 · Berean Standard Bible
And Jonathan had David reaffirm his vow out of love for him, for Jonathan loved David as he loved himself.
Context
15Má ṣe ké àánú rẹ kúrò lórí ìdílé mi títí láé. Bí Olúwa tilẹ̀ ké gbogbo ọ̀tá Dafidi kúrò lórí ilẹ̀.” 16Nígbà náà ni Jonatani bá ilé Dafidi dá májẹ̀mú wí pé, “Olúwa yóò pe àwọn àti Dafidi láti ṣírò.” 17Jonatani mú kí Dafidi tún ìbúra ṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí i, nítorí tí ó fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn ara rẹ̀. 18Nígbà náà ni Jonatani wí fún Dafidi pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a yóò fẹ́ ọ kù, nítorí ààyè rẹ yóò ṣófo. 19Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí ibi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Eselu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.