1 Samuẹli 2:12
1 Samuel 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ Olúwa.
1 Samuel 2:12 in English
1 Samuel 2:12 · Berean Standard Bible
Now the sons of Eli were wicked men; they had no regard for the LORD
Context
10A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;
láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;
Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.
“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,
yóò si gbé ìwo ẹni àmì òróró rẹ̀ sókè.” 11Elkana sì lọ sí Rama, sí ilé rẹ̀, ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà. 12Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ Olúwa. 13Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀. 14Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí àgé tàbí ọpọ́n, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Israẹli tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣilo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.