1 Samuẹli 2:13
1 Samuel 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀.
1 Samuel 2:13 in English
1 Samuel 2:13 · Berean Standard Bible
or for the custom of the priests with the people. When any man offered a sacrifice, the servant of the priest would come with a three-pronged meat fork while the meat was boiling
Context
11Elkana sì lọ sí Rama, sí ilé rẹ̀, ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà. 12Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ Olúwa. 13Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀. 14Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí àgé tàbí ọpọ́n, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Israẹli tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣilo. 15Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfáà; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe tútù.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.