1 Samuẹli 2:11
1 Samuel 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Elkana sì lọ sí Rama, sí ilé rẹ̀, ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà.
1 Samuel 2:11 in English
1 Samuel 2:11 · Berean Standard Bible
Then Elkanah went home to Ramah, but the boy began ministering to the LORD before Eli the priest.
Context
9Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,
àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.
“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí. 10A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;
láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;
Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.
“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,
yóò si gbé ìwo ẹni àmì òróró rẹ̀ sókè.” 11Elkana sì lọ sí Rama, sí ilé rẹ̀, ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà. 12Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ Olúwa. 13Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.