1 Samuẹli 18:3
1 Samuel 18:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jonatani bá Dafidi dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.
1 Samuel 18:3 in English
1 Samuel 18:3 · Berean Standard Bible
Then Jonathan made a covenant with David because he loved him as himself.
Context
1Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá Saulu sọ, ọkàn Jonatani di ọ̀kan pẹ̀lú ti Dafidi, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. 2Láti ọjọ́ náà Saulu pa Dafidi mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́. 3Jonatani bá Dafidi dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. 4Jonatani sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dafidi pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀. 5Ohunkóhun tí Saulu bá rán an láti ṣe, Dafidi máa ṣe ní àṣeyọrí, Saulu náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrín àwọn ológun. Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Saulu lọ́rùn pẹ̀lú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.