1 Samuẹli 18:4
1 Samuel 18:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jonatani sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dafidi pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀.
1 Samuel 18:4 in English
1 Samuel 18:4 · Berean Standard Bible
And Jonathan removed the robe he was wearing and gave it to David, along with his tunic, his sword, his bow, and his belt.
Context
2Láti ọjọ́ náà Saulu pa Dafidi mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́. 3Jonatani bá Dafidi dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. 4Jonatani sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dafidi pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀. 5Ohunkóhun tí Saulu bá rán an láti ṣe, Dafidi máa ṣe ní àṣeyọrí, Saulu náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrín àwọn ológun. Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Saulu lọ́rùn pẹ̀lú. 6Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti pa Filistini, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Israẹli wá láti pàdé ọba Saulu pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tambori àti ohun èlò orin olókùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.