Native Bible

1 Corinthians 9:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi.

1 Corinthians 9:3 in English

1 Corinthians 9:3 · Berean Standard Bible

This is my defense to those who scrutinize me:

Context

1Èmi kò ha ni òmìnira bí? Èmi kò ha ń ṣe aposteli bí? Èmi kò ha ti rí Jesu Olúwa bí? Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí? 2Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe aposteli. Dájúdájú aposteli ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ aposteli mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa. 3Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi. 4Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí? 5Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.