1 Kọrinti 9:4
1 Corinthians 9:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí?
1 Corinthians 9:4 in English
1 Corinthians 9:4 · Berean Standard Bible
Have we no right to food and to drink?
Context
2Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe aposteli. Dájúdájú aposteli ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ aposteli mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa. 3Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi. 4Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí? 5Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa. 6Ṣé èmi nìkan àti Barnaba, àwa kò ha ní agbára láti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa ni?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.