Native Bible

1 Chronicles 6:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

1 Chronicles 6:32 in English

1 Chronicles 6:32 · Berean Standard Bible

They ministered with song before the tabernacle, the Tent of Meeting, until Solomon built the house of the LORD in Jerusalem. And they performed their duties according to the regulations given them.

Context

30Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀ àti Asaiah ọmọ rẹ̀. 31Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀. 32Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn. 33Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati: Hemani olùkọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli, 34ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.