Native Bible

1 Chronicles 29:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ, a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo.

1 Chronicles 29:13 in English

1 Chronicles 29:13 · Berean Standard Bible

Now therefore, our God, we give You thanks, and we praise Your glorious name.

Context

11Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ Olúwa ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo. 12Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo. 13Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ, a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo. 14“Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ. 15Àwa jẹ́ àjèjì àti àlejò ní ojú rẹ gẹ́gẹ́ bí baba ńlá a wa, àwọn ọjọ́ wa lórí ilẹ̀ ayé rí bí òjìji láìsí ìrètí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.