Native Bible

1 Chronicles 29:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ Olúwa ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.

1 Chronicles 29:11 in English

1 Chronicles 29:11 · Berean Standard Bible

Yours, O LORD, is the greatness and the power and the glory and the splendor and the majesty, for everything in heaven and on earth belongs to You. Yours, O LORD, is the kingdom, and You are exalted as head over all.

Context

9Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi. 10Dafidi yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé, “Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa, Ọlọ́run baba a wa Israẹli, láé àti láéláé. 11Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ Olúwa ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo. 12Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo. 13Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ, a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.