1 Kronika 26:10
1 Chronicles 26:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Hosa ará Merari ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣimri alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe àkọ́bí, baba a rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́.
1 Chronicles 26:10 in English
1 Chronicles 26:10 · Berean Standard Bible
Hosah the Merarite also had sons: Shimri the first (although he was not the firstborn, his father had appointed him as the first),
Context
8Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi-Edomu; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Ìran Obedi-Edomu méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo rẹ̀. 9Meṣelemiah ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn. 10Hosa ará Merari ní àwọn ọmọkùnrin:
Ṣimri alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe àkọ́bí, baba a rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́. 11Hilkiah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tabaliah ẹ̀kẹta
àti Sekariah ẹ̀kẹrin.
Àwọn ọmọ àti ìbátan Hosa jẹ́ mẹ́tàlá ni gbogbo rẹ̀. 12Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjíṣẹ́ nínú ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.