Native Bible

1 Chronicles 26:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjíṣẹ́ nínú ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe.

1 Chronicles 26:12 in English

1 Chronicles 26:12 · Berean Standard Bible

These divisions of the gatekeepers, through their chief men, had duties for ministering in the house of the LORD, just as their brothers did.

Context

10Hosa ará Merari ní àwọn ọmọkùnrin: Ṣimri alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe àkọ́bí, baba a rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́. 11Hilkiah ẹlẹ́ẹ̀kejì, Tabaliah ẹ̀kẹta àti Sekariah ẹ̀kẹrin. Àwọn ọmọ àti ìbátan Hosa jẹ́ mẹ́tàlá ni gbogbo rẹ̀. 12Ìpín wọ̀nyí ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà nípasẹ̀ olóyè ọkùnrin wọn, ní iṣẹ́ ìsìn fún jíjíṣẹ́ nínú ilé Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìbátan wọn ti ṣe. 13Wọ́n ṣẹ́ kèké fún ẹnu-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ìdílé wọn bí ọ̀dọ́ àti arúgbó. 14Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣelemiah. Nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Sekariah, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu-ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.