1 Kronika 26:8
1 Chronicles 26:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi-Edomu; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Ìran Obedi-Edomu méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo rẹ̀.
1 Chronicles 26:8 in English
1 Chronicles 26:8 · Berean Standard Bible
All these were descendants of Obed-edom; they and their sons and brothers were capable men with strength to do the work—62 in all from Obed-edom.
Context
6Ọmọ rẹ̀ Ṣemaiah ní àwọn ọmọkùnrin pẹ̀lú tí wọ́n jẹ́ olórí ní ìdílé baba a wọn nítorí wọ́n jẹ́ ọkùnrin tó lágbára. 7Àwọn ọmọ Ṣemaiah:
Otni, Refaeli, Obedi àti Elsabadi;
àwọn ìbátan rẹ̀ Elihu àti Samakiah jẹ́ ọkùnrin alágbára. 8Gbogbo wọ̀nyí ní ìran ọmọ Obedi-Edomu; àwọn àti ọmọkùnrin àti ìbátan wọn jẹ́ alágbára ọkùnrin pẹ̀lú ipá láti ṣe ìsìn náà. Ìran Obedi-Edomu méjìlélọ́gọ́ta ni gbogbo rẹ̀. 9Meṣelemiah ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn. 10Hosa ará Merari ní àwọn ọmọkùnrin:
Ṣimri alákọ́kọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé kì i ṣe àkọ́bí, baba a rẹ̀ ti yàn an ní àkọ́kọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.