Native Bible

1 Chronicles 21:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà angẹli Olúwa náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.

1 Chronicles 21:18 in English

1 Chronicles 21:18 · Berean Standard Bible

Then the angel of the LORD ordered Gad to tell David to go up and build an altar to the LORD on the threshing floor of Ornan the Jebusite.

Context

16Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli Olúwa dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀. 17Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.” 18Nígbà náà angẹli Olúwa náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi. 19Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gadi ti sọ ní orúkọ Olúwa. 20Nígbà tí Arauna sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí angẹli; àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa ará wọn mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.