1 Kronika 21:19
1 Chronicles 21:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gadi ti sọ ní orúkọ Olúwa.
1 Chronicles 21:19 in English
1 Chronicles 21:19 · Berean Standard Bible
So David went up at the word that Gad had spoken in the name of the LORD.
Context
17Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.” 18Nígbà náà angẹli Olúwa náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi. 19Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gòkè lọ pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ tí Gadi ti sọ ní orúkọ Olúwa. 20Nígbà tí Arauna sì ń pakà lọ́wọ́, ó sì yípadà ó sì rí angẹli; àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa ará wọn mọ́. 21Bí Dafidi sì ti dé ọ̀dọ̀ Arauna, Arauna sì wò, ó sì rí Dafidi, ó sì ti ibi ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ jáde, ó sì wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.