Native Bible

1 Chronicles 21:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli Olúwa dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.

1 Chronicles 21:16 in English

1 Chronicles 21:16 · Berean Standard Bible

When David lifted up his eyes and saw the angel of the LORD standing between heaven and earth, with a drawn sword in his hand stretched out over Jerusalem, David and the elders, clothed in sackcloth, fell facedown.

Context

14Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-ààrùn lórí Israẹli, àwọn tí ó ṣubú ní Israẹli jẹ́ ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn. 15Ọlọ́run sì rán angẹli kan sí Jerusalẹmu láti pa wọ́n run. Ṣùgbọ́n bí angẹli ti ń pa wọ́n run, Olúwa sì wò. Ó sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì wí fún angẹli tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Angẹli Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi. 16Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli Olúwa dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀. 17Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.” 18Nígbà náà angẹli Olúwa náà pàṣẹ fún Gadi láti sọ fún Dafidi pé, kí Dafidi kí ó gòkè lọ, kí ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Olúwa lórí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.